Native Bible

Revelation 9:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

A sì tú àwọn angẹli mẹ́rin náà sílẹ̀, tí a ti pèsè tẹ́lẹ̀ fún wákàtí náà, àti ọjọ́ náà, àti oṣù náà, àti ọdún náà, láti pa ìdámẹ́ta ènìyàn.

Revelation 9:15 in English

Revelation 9:15 · Berean Standard Bible

So the four angels who had been prepared for this hour and day and month and year were released to kill a third of mankind.

Context

13Angẹli kẹfà si fọn ìpè rẹ̀, mo sì gbọ́ ohùn kan láti ibi ìwo mẹ́rin pẹpẹ wúrà wá, tí ń bẹ níwájú Ọlọ́run. 14Òun wí fún angẹli kẹfà náà tí o ni ìpè náà pé, “Tú àwọn angẹli mẹ́rin náà sílẹ̀ tí a dè lẹ́bàá odò ńlá Eufurate!” 15A sì tú àwọn angẹli mẹ́rin náà sílẹ̀, tí a ti pèsè tẹ́lẹ̀ fún wákàtí náà, àti ọjọ́ náà, àti oṣù náà, àti ọdún náà, láti pa ìdámẹ́ta ènìyàn. 16Iye ogún àwọn ẹlẹ́ṣin sì jẹ́ àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà igba, mo sì gbọ́ iye wọn. 17Báyìí ni mo sì rí àwọn ẹṣin náà ní ojúran, àti àwọn tí o gùn wọ́n, wọ́n ni ìgbàyà aláwọ̀ iná, àti ti jakinti, àti ti sulfuru, orí àwọn ẹṣin náà sì dàbí orí àwọn kìnnìún; àti láti ẹnu wọn ni iná, àti èéfín, àti sulfuru tí ń jáde.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.