Ìfihàn 9:11
Revelation 9:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n ní angẹli ọ̀gbun náà bí ọba lórí wọn, orúkọ rẹ̀ ní èdè Heberu ní Abaddoni, àti ni èdè Giriki orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Apollioni (èyí ni Apanirun).
Revelation 9:11 in English
Revelation 9:11 · Berean Standard Bible
They were ruled by a king, the angel of the Abyss. His name in Hebrew is Abaddon,* and in Greek it is Apollyon.*
Context
9Wọ́n sì ní ìgbàyà tí ó dàbí ìgbàyà irin; ìró ìyẹ́ wọn sì dàbí ìró kẹ̀kẹ́-ẹṣin púpọ̀ tí ń súré lọ sí ogun. 10Wọ́n sì ni ìrù àti oró bí tí àkéekèe, àti ní ìrù wọn ni agbára wọn wà láti pa ènìyàn lára fún oṣù márùn-ún. 11Wọ́n ní angẹli ọ̀gbun náà bí ọba lórí wọn, orúkọ rẹ̀ ní èdè Heberu ní Abaddoni, àti ni èdè Giriki orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Apollioni (èyí ni Apanirun). 12Ègbé kan tí kọjá, kíyèsi i, ègbé méjì ń bọ̀ síbẹ̀ lẹ́yìn èyí. 13Angẹli kẹfà si fọn ìpè rẹ̀, mo sì gbọ́ ohùn kan láti ibi ìwo mẹ́rin pẹpẹ wúrà wá, tí ń bẹ níwájú Ọlọ́run.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.