Native Bible

Revelation 6:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

A sì ká ọ̀run kúrò bí ìwé tí a ká, àti olúkúlùkù òkè àti erékùṣù ní a sì ṣí kúrò ní ipò wọn.

Revelation 6:14 in English

Revelation 6:14 · Berean Standard Bible

The sky receded like a scroll being rolled up, and every mountain and island was moved from its place.

Context

12Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kẹfà mo sì rí i, sì kíyèsi i, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá kan ṣẹ̀; oòrùn sì dúdú bí aṣọ ọ̀fọ̀ onírun, òṣùpá sì dàbí ẹ̀jẹ̀; 13àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run sì ṣubú sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ń rẹ̀ àìgbó èso rẹ̀ dànù, nígbà tí ẹ̀fúùfù ńlá bá mì í. 14A sì ká ọ̀run kúrò bí ìwé tí a ká, àti olúkúlùkù òkè àti erékùṣù ní a sì ṣí kúrò ní ipò wọn. 15Àwọn ọba ayé àti àwọn ọlọ́lá àti àwọn olórí ogun, àti àwọn ọlọ́rọ̀ àti àwọn alágbára, àti olúkúlùkù ẹrú, àti olúkúlùkù òmìnira, sì fi ara wọn pamọ́ nínú ihò ilẹ̀, àti nínú àpáta orí òkè; 16wọ́n sì ń wí fún àwọn òkè àti àwọn àpáta náà pé, “Ẹ wó lù wá, kí ẹ sì fi wá pamọ́ kúrò lójú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, àti kúrò nínú ìbínú Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.