Ìfihàn 22:5
Revelation 22:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Òru kì yóò sí mọ́; wọn kò sì ní wa ìmọ́lẹ̀ fìtílà, tàbí ìmọ́lẹ̀ oòrùn; nítorí pé Olúwa Ọlọ́run ni yóò tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn: wọn ó sì máa jẹ ọba láé àti láéláé.
Revelation 22:5 in English
Revelation 22:5 · Berean Standard Bible
There will be no more night in the city, and they will have no need for the light of a lamp or of the sun. For the Lord God will shine on them, and they will reign forever and ever.
Context
3Ègún kì yóò sì ṣí mọ: ìtẹ́ Ọlọ́run àti tí Ọ̀dọ́-àgùntàn ni yóò sì máa wà níbẹ̀; àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò sì máa sìn ín. 4Wọ́n ó si máa rí ojú rẹ̀; orúkọ rẹ̀ yóò si máa wà ni iwájú orí wọn. 5Òru kì yóò sí mọ́; wọn kò sì ní wa ìmọ́lẹ̀ fìtílà, tàbí ìmọ́lẹ̀ oòrùn; nítorí pé Olúwa Ọlọ́run ni yóò tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn: wọn ó sì máa jẹ ọba láé àti láéláé. 6Ó sì wí fún mi pé, “Òdodo àti òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: Olúwa Ọlọ́run ẹ̀mí àwọn wòlíì ni ó sì ran angẹli rẹ̀ láti fi ohun tí ó ní láti ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ yìí hàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.” 7“Kíyèsi i, èmi ń bọ̀ kánkán! Ìbùkún ni fún ẹni tí ń pa ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí mọ́!”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.