Native Bible

Revelation 22:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi kìlọ̀ fún olúkúlùkù ẹni tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí pé, bí ẹnikẹ́ni ba fi kún wọn, Ọlọ́run yóò fi kún àwọn ìyọnu tí a kọ sínú ìwé yìí fún un.

Revelation 22:18 in English

Revelation 22:18 · Berean Standard Bible

I testify to everyone who hears the words of prophecy in this book: If anyone adds to them, God will add to him the plagues described in this book.

Context

16“Èmi, Jesu, ni ó rán angẹli mi láti jẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí fún yin ní tí àwọn ìjọ. Èmi ni gbòǹgbò àti irú-ọmọ Dafidi, àti ìràwọ̀ òwúrọ̀ tí ń tàn.” 17Ẹ̀mí àti ìyàwó wí pé, “Máa bọ!” Àti ẹni tí ó ń gbọ́ kí ó wí pé, “Máa bọ̀!” Àti ẹni tí òǹgbẹ ń gbẹ kí ó wá, àti ẹni tí o bá sì fẹ́, kí ó gba omi ìyè náà lọ́fẹ̀ẹ́. 18Èmi kìlọ̀ fún olúkúlùkù ẹni tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí pé, bí ẹnikẹ́ni ba fi kún wọn, Ọlọ́run yóò fi kún àwọn ìyọnu tí a kọ sínú ìwé yìí fún un. 19Bí ẹnikẹ́ni bá sì mú kúrò nínú ọ̀rọ̀ ìwé ìsọtẹ́lẹ̀ yìí, Ọlọ́run yóò sì mú ipa tirẹ̀ kúrò nínú ìwé ìyè, àti kúrò nínú ìlú mímọ́ náà, àti kúrò nínú àwọn ohun tí a kọ sínú ìwé yìí. 20Ẹni tí ó jẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí wí pé, “Nítòótọ́ èmi ń bọ̀ kánkán.” Àmín. Máa bọ̀, Jesu Olúwa!

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.