Native Bible

Revelation 21:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n àwọn ojo, àti aláìgbàgbọ́, àti ẹni ìríra, àti apànìyàn, àti àgbèrè, àti oṣó, àti abọ̀rìṣà, àti àwọn èké gbogbo, ni yóò ni ipa tiwọn nínú adágún tí ń fi iná àti sulfuru jó: èyí tí i ṣe ikú kejì.”

Revelation 21:8 in English

Revelation 21:8 · Berean Standard Bible

But to the cowardly and unbelieving and abominable and murderers and sexually immoral and sorcerers and idolaters and all liars, their place will be in the lake that burns with fire and sulfur. This is the second death.”

Context

6Ó sì wí fún mi pé, “Ó parí. Èmi ni Alfa àti Omega, ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti òpin. Èmi ó sì fi omi fún ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ láti inú orísun omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́. 7Ẹni tí ó ba ṣẹ́gun ni yóò jogún nǹkan wọ̀nyí; èmi ó sì máa jẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, òun ó sì máa jẹ ọmọ mi. 8Ṣùgbọ́n àwọn ojo, àti aláìgbàgbọ́, àti ẹni ìríra, àti apànìyàn, àti àgbèrè, àti oṣó, àti abọ̀rìṣà, àti àwọn èké gbogbo, ni yóò ni ipa tiwọn nínú adágún tí ń fi iná àti sulfuru jó: èyí tí i ṣe ikú kejì.” 9Ọ̀kan nínú àwọn angẹli méje, tí wọ́n ni ago méje, tí ó kún fún ìyọnu méje ìkẹyìn sì wá, ó sì ba mi sọ̀rọ̀ wí pé, “Wá níhìn-ín, èmi ó fi ìyàwó, aya Ọ̀dọ́-àgùntàn hàn ọ́.” 10Ó sì mu mi lọ nínú Ẹ̀mí si òkè ńlá kan tí o sì ga, ó sì fi ìlú náà hàn mi, Jerusalẹmu mímọ́, tí ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.