Native Bible

Revelation 21:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà, sì wí pé, “Kíyèsi i, mo sọ ohun gbogbo di ọ̀tun!” Ó sì wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀, nítorí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí òdodo àti òtítọ́ ni wọ́n.”

Revelation 21:5 in English

Revelation 21:5 · Berean Standard Bible

And the One seated on the throne said, “Behold, I make all things new.” Then He said, “Write this down, for these words are faithful and true.”

Context

3Mo sì gbọ́ ohùn ńlá kan láti orí ìtẹ́ náà wá, ń wí pé, “Kíyèsi i, àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn, òun ó sì máa bá wọn gbé, wọn ó sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀, àti Ọlọ́run tìkára rẹ̀ yóò wà pẹ̀lú wọn, yóò sì máa jẹ́ Ọlọ́run wọn. 4Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ni ojú wọn; kì yóò sì ṣí ikú mọ́, tàbí ọ̀fọ̀, tàbí ẹkún, bẹ́ẹ̀ ni kí yóò sí ìrora mọ́, nítorí pé ohun àtijọ́ tí kọjá lọ.” 5Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà, sì wí pé, “Kíyèsi i, mo sọ ohun gbogbo di ọ̀tun!” Ó sì wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀, nítorí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí òdodo àti òtítọ́ ni wọ́n.” 6Ó sì wí fún mi pé, “Ó parí. Èmi ni Alfa àti Omega, ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti òpin. Èmi ó sì fi omi fún ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ láti inú orísun omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́. 7Ẹni tí ó ba ṣẹ́gun ni yóò jogún nǹkan wọ̀nyí; èmi ó sì máa jẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, òun ó sì máa jẹ ọmọ mi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.