Ìfihàn 20:2
Revelation 20:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
O sì di dragoni náà mú, ejò àtijọ́ nì, tí í ṣe èṣù, àti Satani, ó sì dè é ní ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún.
Revelation 20:2 in English
Revelation 20:2 · Berean Standard Bible
He seized the dragon, that ancient serpent who is the devil and Satan, and bound him for a thousand years.
Context
1Mo sì rí angẹli kan ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, ti òun ti kọ́kọ́rọ́ ọ̀gbun, àti ẹ̀wọ̀n ńlá kan ní ọwọ́ rẹ̀. 2O sì di dragoni náà mú, ejò àtijọ́ nì, tí í ṣe èṣù, àti Satani, ó sì dè é ní ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún. 3Ó sì gbé e sọ sínú ọ̀gbun náà, ó sì tì í, ó sì fi èdìdì dì í lórí rẹ̀, kí ó má ba à tan àwọn orílẹ̀-èdè jẹ mọ́ títí ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún náà yóò fi pé. Lẹ́yìn èyí, a kò le ṣàì tú u sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. 4Mo sì rí àwọn ìtẹ́, wọ́n sì jókòó lórí wọn, a sì fi ìdájọ́ fún wọ́n, mo sì rí ọkàn àwọn tí a ti bẹ́ lórí nítorí ẹ̀rí Jesu, àti nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti àwọn tí kò sì foríbalẹ̀ fún ẹranko náà, àti fún àwòrán rẹ̀, tàbí tí kò sì gbà àmì rẹ̀ ní iwájú wọn àti ní ọwọ́ wọn; wọ́n sì wà láààyè, wọ́n sì jẹ ọba pẹ̀lú Kristi ní ẹgbẹ̀rún (1,000) ọdún.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.