Native Bible

Revelation 20:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

A sì wọ́ Èṣù tí ó tàn wọ́n jẹ lọ sínú adágún iná àti sulfuru, níbi tí ẹranko àti wòlíì èké nì gbé wà, a ó sì máa dá wọn lóró tọ̀sán tòru láé àti láéláé.

Revelation 20:10 in English

Revelation 20:10 · Berean Standard Bible

And the devil who had deceived them was thrown into the lake of fire and sulfur, into which the beast and the false prophet had already been thrown. There they will be tormented day and night forever and ever.

Context

8Yóò sì jáde lọ láti máa tan àwọn orílẹ̀-èdè tí ń bẹ ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé jẹ, Gogu àti Magogu, láti gbá wọn jọ sí ogun: àwọn tí iyè wọn dàbí iyanrìn Òkun. 9Wọ́n sì gòkè lọ la ibú ayé já, wọ́n sì yí ibùdó àwọn ènìyàn mímọ́ ká àti ìlú àyànfẹ́ náà: iná sì ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá, ó sì jó wọn run. 10A sì wọ́ Èṣù tí ó tàn wọ́n jẹ lọ sínú adágún iná àti sulfuru, níbi tí ẹranko àti wòlíì èké nì gbé wà, a ó sì máa dá wọn lóró tọ̀sán tòru láé àti láéláé. 11Mo sì rí ìtẹ́ funfun ńlá kan, àti ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀, níwájú ẹni tí ayé àti ọ̀run fò lọ; a kò sì rí ààyè fún wọn mọ́. 12Mo sì rí àwọn òkú, àti èwe àti àgbà, wọn dúró níwájú ìtẹ́; a sì ṣí àwọn ìwé sílẹ̀; a sì ṣí àwọn ìwé mìíràn kan sílẹ̀ tí í ṣe ìwé ìyè: a sì ṣe ìdájọ́ fún àwọn òkú láti inú ohun tí a ti kọ sínú àwọn ìwé náà, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.