Ìfihàn 19:18
Revelation 19:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ ẹran-ara àwọn ọba, àti ẹran-ara àwọn olórí ogun àti ẹran-ara àwọn ènìyàn alágbára, àti ẹran àwọn ẹṣin, àti ti àwọn tí ó jókòó lórí wọn, àti ẹran-ara ènìyàn gbogbo, àti ti òmìnira, àti ti ẹrú, àti ti èwe àti ti àgbà.”
Revelation 19:18 in English
Revelation 19:18 · Berean Standard Bible
so that you may eat the flesh of kings and commanders and mighty men, of horses and riders, of everyone slave and free, small and great.”
Context
16Ó sì ní lára aṣọ rẹ̀ àti ni ìtàn rẹ̀ orúkọ kan tí a kọ:
Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa. 17Mo sì rí angẹli kan dúró nínú oòrùn; ó sì fi ohùn rara kígbe, ó ń wí fún gbogbo àwọn ẹyẹ tí ń fò ní agbede-méjì ọ̀run pé, “Ẹ wá ẹ sì kó ara yín jọ pọ̀ sí àsè ńlá Ọlọ́run; 18kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ ẹran-ara àwọn ọba, àti ẹran-ara àwọn olórí ogun àti ẹran-ara àwọn ènìyàn alágbára, àti ẹran àwọn ẹṣin, àti ti àwọn tí ó jókòó lórí wọn, àti ẹran-ara ènìyàn gbogbo, àti ti òmìnira, àti ti ẹrú, àti ti èwe àti ti àgbà.” 19Mo sì rí ẹranko náà àti àwọn ọba ayé, àti àwọn ogun wọn tí a gbá jọ láti bá ẹni tí ó jókòó lórí ẹṣin náà àti ogun rẹ̀ jagun. 20A sì mú ẹranko náà, àti wòlíì èké nì pẹ̀lú rẹ̀, tí ó ti ń ṣe iṣẹ́ ìyanu níwájú rẹ̀, èyí tí ó fi ń tan àwọn tí ó gba àmì ẹranko náà àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún àwòrán rẹ̀ jẹ. Àwọn méjèèjì yìí ni a sọ láààyè sínú adágún iná tí ń fi sulfuru jó.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.