Ìfihàn 19:15
Revelation 19:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àti láti ẹnu rẹ̀ ni idà mímú ti ń jáde lọ, kí ó lè máa fi sá àwọn orílẹ̀-èdè: “Òun ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn.” Ó sì ń tẹ ìfúntí àti ìbínú Ọlọ́run Olódùmarè.
Revelation 19:15 in English
Revelation 19:15 · Berean Standard Bible
And from His mouth proceeds a sharp sword with which to strike down the nations, and He will rule them with an iron scepter.* He treads the winepress of the fury of the wrath of God the Almighty.
Context
13A sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ tí a tẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀, a sì ń pe orúkọ rẹ̀ ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 14Àwọn ogun tí ń bẹ ní ọ̀run tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, funfun àti mímọ́, sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn lórí ẹṣin funfun. 15Àti láti ẹnu rẹ̀ ni idà mímú ti ń jáde lọ, kí ó lè máa fi sá àwọn orílẹ̀-èdè: “Òun ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn.” Ó sì ń tẹ ìfúntí àti ìbínú Ọlọ́run Olódùmarè. 16Ó sì ní lára aṣọ rẹ̀ àti ni ìtàn rẹ̀ orúkọ kan tí a kọ:
Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa. 17Mo sì rí angẹli kan dúró nínú oòrùn; ó sì fi ohùn rara kígbe, ó ń wí fún gbogbo àwọn ẹyẹ tí ń fò ní agbede-méjì ọ̀run pé, “Ẹ wá ẹ sì kó ara yín jọ pọ̀ sí àsè ńlá Ọlọ́run;
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.