Ìfihàn 17:4
Revelation 17:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
A sì fi aṣọ elése àlùkò àti aṣọ òdòdó wọ obìnrin náà, a sì fi wúrà àti òkúta iyebíye àti perli ṣe é ní ọ̀ṣọ́, ó ní ago wúrà kan ní ọwọ́ rẹ̀, tí ó kún fún ìríra àti fún ẹ̀gbin àgbèrè rẹ̀;
Revelation 17:4 in English
Revelation 17:4 · Berean Standard Bible
The woman was dressed in purple and scarlet, and adorned with gold and precious stones and pearls. She held in her hand a golden cup full of abominations and the impurities of her sexual immorality.
Context
2ẹni tí àwọn ọba ayé bá ṣe àgbèrè, tí a sì fi ọtí wáìnì àgbèrè rẹ̀ pa àwọn tí ń gbé inú ayé.” 3Ó sì gbé mi nínú ẹ̀mí lọ sí aginjù: mo sì rí obìnrin kan ó jókòó lórí ẹranko aláwọ̀ òdòdó kan tí ó kún fún orúkọ ọ̀rọ̀-òdì, ó ní orí méje àti ìwo mẹ́wàá. 4A sì fi aṣọ elése àlùkò àti aṣọ òdòdó wọ obìnrin náà, a sì fi wúrà àti òkúta iyebíye àti perli ṣe é ní ọ̀ṣọ́, ó ní ago wúrà kan ní ọwọ́ rẹ̀, tí ó kún fún ìríra àti fún ẹ̀gbin àgbèrè rẹ̀; 5àti níwájú rẹ̀ ni orúkọ kan tí a kọ:
Ohun ìjìnlẹ̀ Babeli ńlá
ìyá àwọn panṣágà
àti àwọn ohun ìríra ayé. 6Mo sì rí obìnrin náà mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́, àti ẹ̀jẹ̀ àwọn ajẹ́rìí ikú Jesu ní àmuyó.
Nígbà tí mo sì rí i, ẹnu yà mi gidigidi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.