Ìfihàn 17:14
Revelation 17:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn wọ̀nyí ni yóò si máa bá Ọ̀dọ́-Àgùntàn jagun, Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà yóò sì ṣẹ́gun wọn: nítorí òun ni Olúwa àwọn Olúwa, àti ọba àwọn ọba: àwọn tí ó sì wà pẹ̀lú rẹ̀, tí a pè, tí a yàn, tí wọ́n sì jẹ́ olóòtítọ́ yóò sì ṣẹ́gun pẹ̀lú.”
Revelation 17:14 in English
Revelation 17:14 · Berean Standard Bible
They will make war against the Lamb, and the Lamb will triumph over them, because He is Lord of lords and King of kings; and He will be accompanied by His called and chosen and faithful ones.”
Context
12“Ìwo mẹ́wàá tí ìwọ sì rí ni ọba mẹ́wàá ni wọn, tí wọn kò ì ti gba ìjọba; ṣùgbọ́n wọn gba àṣẹ bí ọba pẹ̀lú ẹranko náà fún wákàtí kan. 13Àwọn wọ̀nyí ní inú kan, wọ́n yóò sì fi agbára àti ọlá wọn fún ẹranko náà. 14Àwọn wọ̀nyí ni yóò si máa bá Ọ̀dọ́-Àgùntàn jagun, Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà yóò sì ṣẹ́gun wọn: nítorí òun ni Olúwa àwọn Olúwa, àti ọba àwọn ọba: àwọn tí ó sì wà pẹ̀lú rẹ̀, tí a pè, tí a yàn, tí wọ́n sì jẹ́ olóòtítọ́ yóò sì ṣẹ́gun pẹ̀lú.” 15Ó sì wí fún mi pé, “Àwọn omi tí ìwọ ti rí ni, níbi tí àgbèrè náà jókòó, àwọn ènìyàn àti ẹ̀yà àti orílẹ̀ àti onírúurú èdè ni wọ́n. 16Àti ìwo mẹ́wàá tí ìwọ rí, àti ẹranko náà, àwọn wọ̀nyí ni yóò kórìíra àgbèrè náà, wọn ó sì sọ ọ́ di ahoro àti ẹni ìhòhò, wọn ó sì jẹ ẹran-ara rẹ̀, wọn ó sì fi iná sun ún pátápátá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.