Ìfihàn 16:19
Revelation 16:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìlú ńlá náà sì pín sí ipa mẹ́ta, àwọn orílẹ̀-èdè sì ṣubú: Babeli ńlá sì wá sí ìrántí níwájú Ọlọ́run, láti fi ago ọtí wáìnì ti ìrunú ìbínú rẹ̀ fún un.
Revelation 16:19 in English
Revelation 16:19 · Berean Standard Bible
The great city was split into three parts, and the cities of the nations collapsed. And God remembered Babylon the great and gave her the cup of the wine of the fury of His wrath.
Context
17Èkeje si tú ago tirẹ̀ sí ojú ọ̀run; ohùn ńlá kan sì ti inú tẹmpili jáde láti ibi ìtẹ́, wí pé, “Ó parí!” 18Mọ̀nàmọ́ná sì kọ, a sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá sì ṣẹ̀, irú èyí tí kò ṣẹ̀ ri láti ìgbà tí ènìyàn ti wà lórí ilẹ̀, irú ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá bẹ́ẹ̀, tí ó sì lágbára tó bẹ́ẹ̀. 19Ìlú ńlá náà sì pín sí ipa mẹ́ta, àwọn orílẹ̀-èdè sì ṣubú: Babeli ńlá sì wá sí ìrántí níwájú Ọlọ́run, láti fi ago ọtí wáìnì ti ìrunú ìbínú rẹ̀ fún un. 20Olúkúlùkù erékùṣù sì sálọ, a kò sì ri àwọn òkè ńlá mọ́. 21Yìnyín ńlá, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan rẹ̀ tó tálẹ́ǹtì ní ìwọ̀n, sì bọ́ lù àwọn ènìyàn láti ọ̀run wà, àwọn ènìyàn sì sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run nítorí ìyọnu yìnyín náà; nítorí tí ìyọnu rẹ̀ náà pọ̀ gidigidi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.