Ìfihàn 14:9
Revelation 14:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Angẹli mìíràn, ẹ̀kẹta, sì tẹ̀lé wọn, ó ń wí ni ohùn rara pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá ń foríbalẹ̀ fún ẹranko náà àti àwòrán rẹ̀, tí ó sì gba àmì sí iwájú orí rẹ̀ tàbí sí ọwọ́ rẹ̀.
Revelation 14:9 in English
Revelation 14:9 · Berean Standard Bible
And a third angel followed them, calling out in a loud voice, “If anyone worships the beast and its image, and receives its mark on his forehead or on his hand,
Context
7Ó ń wí ni ohùn rara pé, “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí tí wákàtí ìdájọ́ rẹ̀ dé: ẹ sì foríbalẹ̀ fún ẹni tí o dá ọ̀run, àti ayé, àti Òkun, àti àwọn orísun omi!” 8Angẹli mìíràn sì tẹ̀lé e, ó ń wí pé, “o ṣubú, Babeli ńlá ṣubú, èyí ti o tí ń mú gbogbo orílẹ̀-èdè mu nínú ọtí wáìnì àìmọ́ àgbèrè rẹ̀!” 9Angẹli mìíràn, ẹ̀kẹta, sì tẹ̀lé wọn, ó ń wí ni ohùn rara pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá ń foríbalẹ̀ fún ẹranko náà àti àwòrán rẹ̀, tí ó sì gba àmì sí iwájú orí rẹ̀ tàbí sí ọwọ́ rẹ̀. 10Òun pẹ̀lú yóò mú nínú ọtí wáìnì ìbínú Ọlọ́run, tí a dà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ sínú ago ìrunú rẹ̀; a ó sì fi iná sulfuru dá a lóró níwájú àwọn angẹli mímọ́, àti níwájú Ọ̀dọ́-àgùntàn. 11Èéfín ìdálóró wọn ń lọ sókè títí láéláé wọn kò sì ní ìsinmi ni ọ̀sán àti ní òru, àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún ẹranko náà àti fún àwòrán rẹ̀, àti ẹnikẹ́ni tí o ba sì gba àmì orúkọ rẹ̀.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.