Native Bible

Revelation 14:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá, bí ariwo omi púpọ̀, àti bí sísán àrá ńlá, mo sì gbọ́ àwọn aludùùrù tí wọn ń lu dùùrù.

Revelation 14:2 in English

Revelation 14:2 · Berean Standard Bible

And I heard a sound from heaven like the roar of many waters and the loud rumbling of thunder. And the sound I heard was like harpists strumming their harps.

Context

1Mo sì wo, si kíyèsi i, Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà dúró lórí òkè Sioni, àti pẹ̀lú rẹ̀ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) ènìyàn; wọ́n ní orúkọ rẹ̀, àti orúkọ baba rẹ̀ tí a kọ sí iwájú orí wọn. 2Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá, bí ariwo omi púpọ̀, àti bí sísán àrá ńlá, mo sì gbọ́ àwọn aludùùrù tí wọn ń lu dùùrù. 3Wọ́n sì ń kọ bí ẹni pé orin tuntun níwájú ìtẹ́ náà, àti níwájú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin n nì àti àwọn àgbà náà, kò sì ṣí ẹni tí o lè kọ orin náà, bí kò ṣe àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) ènìyàn, tí a tí rà padà láti inú ayé wá. 4Àwọn wọ̀nyí ni a kò fi obìnrin sọ di èérí, nítorí tí wọ́n jẹ́ wúńdíá. Àwọn wọ̀nyí ni o ń tọ Ọ̀dọ́-àgùntàn náà lẹ́yìn níbikíbi tí o bá ń lọ. Àwọn wọ̀nyí ni a rà padà láti inú àwọn ènìyàn wá, wọ́n jẹ́ àkọ́so fún Ọlọ́run àti fún Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.