Ìfihàn 14:12
Revelation 14:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Níhìn-ín ni sùúrù àwọn ènìyàn mímọ́ gbé wà: àwọn tí ń pa òfin Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ Jesu mọ́.
Revelation 14:12 in English
Revelation 14:12 · Berean Standard Bible
Here is a call for the perseverance of the saints who keep the commandments of God and the faith of Jesus.
Context
10Òun pẹ̀lú yóò mú nínú ọtí wáìnì ìbínú Ọlọ́run, tí a dà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ sínú ago ìrunú rẹ̀; a ó sì fi iná sulfuru dá a lóró níwájú àwọn angẹli mímọ́, àti níwájú Ọ̀dọ́-àgùntàn. 11Èéfín ìdálóró wọn ń lọ sókè títí láéláé wọn kò sì ní ìsinmi ni ọ̀sán àti ní òru, àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún ẹranko náà àti fún àwòrán rẹ̀, àti ẹnikẹ́ni tí o ba sì gba àmì orúkọ rẹ̀.” 12Níhìn-ín ni sùúrù àwọn ènìyàn mímọ́ gbé wà: àwọn tí ń pa òfin Ọlọ́run àti ìgbàgbọ́ Jesu mọ́. 13Mo sì gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run wá ń wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀, Alábùkún fún ni àwọn òkú tí o kú nínú Olúwa láti ìhín lọ.”
Alábùkún ni wọ́n nítòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni, Ẹ̀mí wí, “Nítorí tí wọn yóò sinmi kúrò nínú làálàá wọn, nítorí iṣẹ́ wọn ń tọ̀ wọn lẹ́yìn.” 14Mo sì wo, sì kíyèsi i, ìkùùkuu àwọsánmọ̀ funfun kan, àti lórí ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà ẹnìkan jókòó tí o dàbí “ọmọ ènìyàn,” tí òun ti adé wúrà ní orí rẹ̀, àti dòjé mímú ni ọwọ́ rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.