Native Bible

Revelation 13:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

A sì fún un ni ẹnu láti má sọ ohun ńlá àti ọ̀rọ̀-òdì, a sì fi agbára fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ ni oṣù méjìlélógójì.

Revelation 13:5 in English

Revelation 13:5 · Berean Standard Bible

The beast was given a mouth to speak arrogant and blasphemous words, and authority to act for 42 months.

Context

3Mo sì rí ọ̀kan nínú àwọn orí rẹ̀ bí ẹni pé a sá a pa, a sì tí wo ọgbẹ́ àṣápa rẹ̀ náà sàn, gbogbo ayé sì fi ìyanu tẹ̀lé ẹranko náà. 4Wọ́n sì foríbalẹ̀ fún dragoni náà, nítorí tí o fún ẹranko náà ní àṣẹ, wọn sì foríbalẹ̀ fún ẹranko náà, wí pé, “Ta ni o dàbí ẹranko yìí? Ta ni ó sì lè bá a jagun?” 5A sì fún un ni ẹnu láti má sọ ohun ńlá àti ọ̀rọ̀-òdì, a sì fi agbára fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ ni oṣù méjìlélógójì. 6Ó sì ya ẹnu rẹ̀ ni ọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run, láti sọ ọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ rẹ̀, àti sí àgọ́ rẹ̀, àti sí àwọn tí ń gbé ọ̀run. 7A sì fún un láti máa bá àwọn ènìyàn mímọ́ jagun, àti láti ṣẹ́gun wọn, a sì fi agbára fún un lórí gbogbo ẹ̀yà, àti ènìyàn, àti èdè, àti orílẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.