Native Bible

Revelation 13:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì mu gbogbo wọn, àti kékeré àti ńlá, ọlọ́rọ̀ àti tálákà, olómìnira àti ẹrú, láti gba àmì kan sí ọwọ́ ọ̀tún wọn, tàbí ní iwájú orí wọn;

Revelation 13:16 in English

Revelation 13:16 · Berean Standard Bible

And the second beast required all people small and great, rich and poor, free and slave, to receive a mark on their right hand or on their forehead,

Context

14Ó sì ń tán àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé jẹ nípa àwọn ohun ìyanu tí a fi fún un láti ṣe níwájú ẹranko náà; ó wí fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé láti ya àwòrán fún ẹranko náà tí o tí gbá ọgbẹ́ idà, tí ó sì yè. 15A sì fi fún un, láti fi ẹ̀mí fún àwòrán ẹranko náà kí ó máa sọ̀rọ̀ kí ó sì mu kí a pa gbogbo àwọn tí kò foríbalẹ̀ fún àwòrán ẹranko náà. 16Ó sì mu gbogbo wọn, àti kékeré àti ńlá, ọlọ́rọ̀ àti tálákà, olómìnira àti ẹrú, láti gba àmì kan sí ọwọ́ ọ̀tún wọn, tàbí ní iwájú orí wọn; 17àti kí ẹnikẹ́ni má lè rà tàbí tà, bí kò ṣe ẹni tí o bá ní àmì náà, èyí ni orúkọ ẹranko náà, tàbí àmì orúkọ rẹ̀. 18Níhìn-ín ni ọgbọ́n gbé wà. Ẹni tí o bá ní òye, kí o ka òǹkà tí ń bẹ̀ lára ẹranko náà, nítorí pé òǹkà ènìyàn ni, òǹkà rẹ̀ náà sì jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà (666).

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.