Ìfihàn 1:7
Revelation 1:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Kíyèsi i, o ń bọ̀ nínú àwọsánmọ̀, gbogbo ojú ni yóò sì rí i, àti àwọn tí ó gún un ní ọ̀kọ̀ pẹ̀lú”; àti gbogbo orílẹ̀-èdè ayé ni “yóò sì máa pohùnréré ẹkún nítorí rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ náà ni! Àmín.
Revelation 1:7 in English
Revelation 1:7 · Berean Standard Bible
Behold, He is coming with the clouds, and every eye will see Him—even those who pierced Him. And all the tribes of the earth will mourn because of Him. So shall it be! Amen.
Context
5àti láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, ẹlẹ́rìí olóòtítọ́, àkọ́bí nínú àwọn òkú, àti aláṣẹ àwọn ọba ayé.
Ẹni tí ó fẹ́ wa, ẹni tí ó gbà wá kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, 6tí ó sì ti fi wá jẹ ọba àti àlùfáà láti sin Ọlọ́run àti Baba rẹ; tirẹ̀ ni ògo àti ìjọba láé àti láéláé. Àmín. 7“Kíyèsi i, o ń bọ̀ nínú àwọsánmọ̀,
gbogbo ojú ni yóò sì rí i,
àti àwọn tí ó gún un ní ọ̀kọ̀ pẹ̀lú”;
àti gbogbo orílẹ̀-èdè ayé ni
“yóò sì máa pohùnréré ẹkún nítorí rẹ̀.”
Bẹ́ẹ̀ náà ni! Àmín. 8“Èmi ni Alfa àti Omega,” ni Olúwa Ọlọ́run wí, “ẹni tí ó ń bẹ, tí ó ti wà, tí ó sì ń bọ̀ wá, alágbára.” 9Èmi, Johanu, arákùnrin yín àti alábápín pẹ̀lú yín nínú wàhálà àti ìjọba àti sùúrù tí ń bẹ nínú Jesu, wà ní erékúṣù tí a ń pè ní Patmo, nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti nítorí ẹ̀rí Jesu Kristi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.