Ìfihàn 1:4
Revelation 1:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Johanu, Sí àwọn ìjọ méje tí ń bẹ ní Asia: Oore-ọ̀fẹ́ fún yín, àti àlàáfíà, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ń bẹ, tí ó sì ti wà, tí ó sì ń bọ̀ wá; àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí méje tí ń bẹ níwájú ìtẹ́ rẹ̀;
Revelation 1:4 in English
Revelation 1:4 · Berean Standard Bible
John, To the seven churches in the province of Asia:* Grace and peace to you from Him who is and was and is to come, and from the seven Spirits * before His throne,
Context
2ẹni tí ó jẹ́rìí ohun gbogbo tí ó rí, èyí ì ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti ẹ̀rí ti Jesu Kristi. 3Ẹni ìbùkún ni ẹni tí ń kà, àti àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ yìí, tí ó sì ń pa nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a kọ sínú rẹ̀ mọ́, nítorí ìgbà kù sí dẹ̀dẹ̀. 4Johanu,
Sí àwọn ìjọ méje tí ń bẹ ní Asia:
Oore-ọ̀fẹ́ fún yín, àti àlàáfíà, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ń bẹ, tí ó sì ti wà, tí ó sì ń bọ̀ wá; àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí méje tí ń bẹ níwájú ìtẹ́ rẹ̀; 5àti láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, ẹlẹ́rìí olóòtítọ́, àkọ́bí nínú àwọn òkú, àti aláṣẹ àwọn ọba ayé.
Ẹni tí ó fẹ́ wa, ẹni tí ó gbà wá kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, 6tí ó sì ti fi wá jẹ ọba àti àlùfáà láti sin Ọlọ́run àti Baba rẹ; tirẹ̀ ni ògo àti ìjọba láé àti láéláé. Àmín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.