Ìfihàn 1:16
Revelation 1:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì ní ìràwọ̀ méje ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀; àti láti ẹnu rẹ̀ wá ni idà olójú méjì mímú ti jáde. Ojú rẹ̀ sì dàbí oòrùn tí ó ń fi agbára rẹ̀ hàn.
Revelation 1:16 in English
Revelation 1:16 · Berean Standard Bible
He held in His right hand seven stars, and a sharp double-edged sword came from His mouth. His face was like the sun shining at its brightest.
Context
14Orí rẹ̀ àti irun rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú, ó funfun bí yìnyín; ojú rẹ̀ sì dàbí, ọwọ́ iná. 15Ẹsẹ̀ rẹ̀ sì dàbí idẹ dáradára, bí ẹni pé a dà á nínú ìléru; ohùn rẹ̀ sì dàbí ìró omi púpọ̀. 16Ó sì ní ìràwọ̀ méje ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀; àti láti ẹnu rẹ̀ wá ni idà olójú méjì mímú ti jáde. Ojú rẹ̀ sì dàbí oòrùn tí ó ń fi agbára rẹ̀ hàn. 17Nígbà tí mo rí i, mo wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ bí ẹni tí ó kú. Ó sì fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé mi, ó ń wí fún mi pé, “Má ṣe bẹ̀rù. Èmi ni ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn. 18Èmi ni ẹni tí ó ń bẹ láààyè, tí ó sì ti kú; sì kíyèsi i, èmi sì ń bẹ láààyè sí i títí láé! Mo sì ní kọ́kọ́rọ́ ikú àti ti ipò òkú lọ́wọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.