Native Bible

Revelation 1:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

àti láàrín àwọn ọ̀pá fìtílà náà, ẹnìkan tí ó dàbí “ọmọ ènìyàn,” tí a wọ̀ ní aṣọ tí ó kanlẹ̀ dé ẹsẹ̀, tí a sì fi àmùrè wúrà dì ní ẹ̀gbẹ́.

Revelation 1:13 in English

Revelation 1:13 · Berean Standard Bible

and among the lampstands was One like the Son of Man,* dressed in a long robe, with a golden sash around His chest.

Context

11Ó ń wí pé, “Kọ́ ìwé rẹ̀, ohun tí ìwọ rí, kí ó sí fi ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ méje; sí Efesu, àti sí Smirna, àti sí Pargamu, àti sí Tiatira, àti sí Sardi, àti sí Filadelfia, àti sí Laodikea.” 12Mo sì yí padà láti wo ohùn tí ń bá mi sọ̀rọ̀. Nígbà tí mo yípadà, mo rí ọ̀pá fìtílà wúrà méje, 13àti láàrín àwọn ọ̀pá fìtílà náà, ẹnìkan tí ó dàbí “ọmọ ènìyàn,” tí a wọ̀ ní aṣọ tí ó kanlẹ̀ dé ẹsẹ̀, tí a sì fi àmùrè wúrà dì ní ẹ̀gbẹ́. 14Orí rẹ̀ àti irun rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú, ó funfun bí yìnyín; ojú rẹ̀ sì dàbí, ọwọ́ iná. 15Ẹsẹ̀ rẹ̀ sì dàbí idẹ dáradára, bí ẹni pé a dà á nínú ìléru; ohùn rẹ̀ sì dàbí ìró omi púpọ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.