Saamu 96
Psalms 96 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
1Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa,
ẹ kọrin sí Olúwa gbogbo ayé. 2Ẹ kọrin sí Olúwa, yin orúkọ rẹ̀
ẹ sọ ti ìgbàlà rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́. 3Ẹ sọ ti ògo rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè
àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrín gbogbo ènìyàn. 4Nítorí títóbi ní Olúwa ẹni tí ìyìn tọ́ sí;
òun ní o yẹ kí a bẹ̀rù ju gbogbo òrìṣà lọ. 5Nítorí asán ni gbogbo àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè
ṣùgbọ́n Olúwa dá àwọn ọ̀run. 6Ọlá àti ọláńlá wà ní iwájú rẹ̀
agbára àti ògo wà ní ibi mímọ́ rẹ̀. 7Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ìbátan ènìyàn,
ẹ fi agbára àti ògo fún Olúwa. 8Ẹ fi ògo tí ó tọ́ sí Olúwa fún un;
ẹ mú ọrẹ wá, kí ẹ sì wá sí àgbàlá rẹ̀. 9Ẹ máa sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́ rẹ̀;
ẹ wárìrì níwájú rẹ̀ gbogbo ayé. 10Sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, “Olúwa jẹ ọba.”
A fi ìdí ayé múlẹ̀, tí kò sì lè yí;
ẹni tí yóò fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ ènìyàn. 11Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, kí ayé sì pariwo
jẹ́ kí pápá òkun kí ó hó pẹ̀lú ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀. 12Jẹ́ kí oko kún fún ayọ̀, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀;
nígbà náà ni gbogbo igi igbó yóò máa yọ̀. 13Wọn yóò kọrin níwájú Olúwa,
nítorí tí ó ń bọ̀ wá, ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé.
Yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé
àti ti àwọn ènìyàn ni yóò fi òtítọ́ rẹ̀ ṣe.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.