Saamu 84
Psalms 84 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
1Ibùgbé rẹ̀ ti lẹ́wà tó,
Olúwa àwọn ọmọ-ogun! 2Ọkàn mi ń ṣàfẹ́rí nítòótọ́
ó tilẹ̀ pòǹgbẹ fún àgbàlá Olúwa
àyà mi àti ara mi ń kọrin ayọ̀
sí Ọlọ́run alààyè. 3Nítòótọ́ ológoṣẹ́ ri ilé,
ẹyẹ alápáǹdẹ̀dẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ fún ara rẹ̀,
níbi tí yóò máa pa ọmọ rẹ̀ mọ́ sí:
ibùgbé ní tòsí pẹpẹ rẹ̀,
Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ọba mí àti Ọlọ́run mi. 4Ìbùkún ní fún àwọn tí ó ń gbé inú ilé rẹ;
wọn ó máa yìn ọ́ títí láé. 5Ìbùkún ni fún àwọn tí agbára wọn wà nínú rẹ
àwọn tí wọ́n gbé ọkàn lé bíbẹ ibi mímọ́ wò. 6Àwọn tí ń la àfonífojì omijé lọ
wọn sọ ọ́ di kànga
àkọ́rọ̀ òjò sì fi ìbùkún bò ó. 7Wọ́n ń lọ láti ipa dé ipá
títí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan fi farahàn níwájú Ọlọ́run ní Sioni. 8Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa Ọlọ́run Alágbára;
tẹ́tí sí mi, Ọlọ́run Jakọbu. 9Wo asà wa, Ọlọ́run;
fi ojú àánú wò àwọn ẹni àmì òróró rẹ. 10Dídára ní ọjọ́ kan ní ààfin rẹ
ju ẹgbẹ̀rún (1,000) ọjọ́ lọ;
èmi o kúkú máa ṣe aṣọ́nà nínú ilé Ọlọ́run mi
jù láti gbé ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú. 11Nítorí Olúwa Ọlọ́run jẹ́ òòrùn àti asà;
Olúwa fún ni ní ojúrere àti ọlá;
kò sí ohun rere kan tí yóò fàsẹ́yìn
fún àwọn tí ó rìn ní àìlábùkù. 12Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.