Native Bible

Psalms 78:38 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Síbẹ̀ ó ṣàánú; ó dárí àìṣedéédéé wọn jì òun kò sì pa wọ́n run nígbà púpọ̀ ló ń yí ìbínú rẹ̀ padà kò sì ru ìbínú rẹ̀ sókè

Psalms 78:38 in English

Psalms 78:38 · Berean Standard Bible

And yet He was compassionate; He forgave their iniquity and did not destroy them. He often restrained His anger and did not unleash His full wrath.

Context

36Ṣùgbọ́n nígbà náà ni wọ́n yóò pọ́n ọn pẹ̀lú ẹnu wọ́n wọ́n fi ahọ́n wọ́n purọ́ fún un; 37ọkàn wọn kò sòtítọ́ sí i, wọn kò jẹ́ olódodo sí májẹ̀mú rẹ̀. 38Síbẹ̀ ó ṣàánú; ó dárí àìṣedéédéé wọn jì òun kò sì pa wọ́n run nígbà púpọ̀ ló ń yí ìbínú rẹ̀ padà kò sì ru ìbínú rẹ̀ sókè 39Ó rántí pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n, afẹ́fẹ́ tó ń kọjá tí kò lè padà. 40Nígbà gbogbo ní wọn ń ṣọ̀tẹ̀ sí i ní aginjù wọn mú un bínú nínú ilẹ̀ tí ó di ahoro!

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.