Saamu 77:2
Psalms 77:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí mo wà nínú ìpọ́njú, mo wá Olúwa; ní òru ni mo na ọwọ́ mi jáde ní àìkáárẹ̀ ọkàn mí sì kọ̀ láti tù ú nínú.
Psalms 77:2 in English
Psalms 77:2 · Berean Standard Bible
In the day of trouble I sought the Lord; through the night my outstretched hands did not grow weary; my soul refused to be comforted.
Context
1Mó kígbe sí Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́;
mo kígbe sí Ọlọ́run láti gbọ́ tèmi. 2Nígbà tí mo wà nínú ìpọ́njú,
mo wá Olúwa;
ní òru ni mo na ọwọ́ mi jáde ní àìkáárẹ̀
ọkàn mí sì kọ̀ láti tù ú nínú. 3Èmi rántí rẹ, Ọlọ́run,
mo sì kẹ́dùn;
mo ṣe àròyé, ẹ̀mí mi sì rẹ̀wẹ̀sì. Sela. 4Ìwọ kò fẹ́ kí èmi fi ojú ba oorun,
mo dààmú tó bẹ́ẹ̀ tí ń kò le sọ̀rọ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.