Native Bible

Psalms 77:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi ó rántí iṣẹ́ Olúwa: bẹ́ẹ̀ ni, èmi ó rántí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ọjọ́ pípẹ́.

Psalms 77:11 in English

Psalms 77:11 · Berean Standard Bible

I will remember the works of the LORD; yes, I will remember Your wonders of old.

Context

9Ọlọ́run ha gbàgbé láti máa ṣàánú? Ní ìbínú rẹ̀, ó ha sé ojúrere rẹ̀ mọ́?” Sela. 10Èmi wí pé, “Èyí ní ẹ̀dùn ọkàn mi, pé ọwọ́ ọ̀tún Ọ̀gá-ògo jùlọ ti yípadà”. 11Èmi ó rántí iṣẹ́ Olúwa: bẹ́ẹ̀ ni, èmi ó rántí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ọjọ́ pípẹ́. 12Èmi ṣàṣàrò lórí iṣẹ́ rẹ gbogbo, pẹ̀lú, ènìyàn sì máa sọ̀rọ̀ gbogbo iṣẹ́ agbára rẹ. 13Ọlọ́run, ọ̀nà rẹ jẹ́ mímọ́. Ọlọ́run wo ni ó sì tóbi bí Ọlọ́run wa?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.