Saamu 75
Psalms 75 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
1A fi ìyìn fún ọ, Ọlọ́run,
a yìn ọ́, nítorí orúkọ rẹ súnmọ́ tòsí;
àwọn ènìyàn ń sọ ti ìyanu rẹ. 2Ìwọ wí pé, “Mo yan àkókò ìyàsọ́tọ̀;
Èmi ni ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ òdodo. 3Nígbà tí ayé àti àwọn ènìyàn ibẹ̀ wárìrì,
Èmi ni mo di òpó rẹ̀ mú ṣinṣin. 4Èmí wí fún àwọn agbéraga pé,
ẹ má ṣe gbéraga mọ́;
àti sí ènìyàn búburú;
ẹ má ṣe gbé ìwo yín sókè. 5Ẹ má ṣe gbe ìwo yín sókè sí ọ̀run;
ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọrùn líle.” 6Nítorí ìgbéga kò ti ìlà-oòrùn wá
tàbí ní ìwọ̀-oòrùn,
bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe láti gúúsù wá. 7Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni olùdájọ́;
Ó ń rẹ ẹnìkan sílẹ̀, ó sì ń gbé ẹlòmíràn ga. 8Ní ọwọ́ Olúwa ni ago kan wà,
ọtí wáìnì náà sì pọ́n, ó kún fún àdàlú,
ó fún ọtí àdàlú tí a pò mọ́ òórùn dídùn tí ó tú jáde,
àwọn ènìyàn búburú ayé gbogbo mú u pátápátá. 9Ṣùgbọ́n èmi, ó máa ròyìn rẹ títí láé;
èmi ó kọrin ìyìn sí Ọlọ́run Jakọbu. 10Èmi ó gé ìwo gbogbo ènìyàn búburú,
ṣùgbọ́n ìwo àwọn olódodo ni a ó gbéga.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.