Native Bible

Psalms 58:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olódodo yóò yọ̀ nígbà a bá ń gbẹ̀san wọn, nígbà tí wọn bá wẹ ẹsẹ̀ wọn nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn búburú.

Psalms 58:10 in English

Psalms 58:10 · Berean Standard Bible

The righteous will rejoice when they see they are avenged; they will wash their feet in the blood of the wicked.

Context

8Jẹ́ kí wọn rí bí ìgbín tí rẹ̀ dànù tí ó sì ṣègbé bí ọmọ tí oṣù rẹ̀ kò pé, kí wọn má ṣe rí oòrùn. 9Kí ìkòkò yín kí ó tó mọ ìgbóná ẹ̀gún; bóyá ní tútù tàbí ní gbígbẹ, yóò fi ìjì gbá wọn lọ. 10Olódodo yóò yọ̀ nígbà a bá ń gbẹ̀san wọn, nígbà tí wọn bá wẹ ẹsẹ̀ wọn nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn búburú. 11Àwọn ènìyàn yóò wí pé, “Lóòtítọ́ èrè àwọn ń bẹ fún olódodo; lóòtítọ́ òun ni Ọlọ́run tí ń ṣe ìdájọ́ ní ayé.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.