Native Bible

Psalms 41:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Pàápàá, ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé, ẹni tí ó ń jẹ nínú oúnjẹ mi, tí gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sókè sí mi.

Psalms 41:9 in English

Psalms 41:9 · Berean Standard Bible

Even my close friend whom I trusted, the one who shared my bread, has lifted up his heel against me.*

Context

7Àwọn ọ̀tá mi gbìmọ̀ papọ̀ nípa mi; èmi ni wọ́n ń gbìmọ̀ ibi sí, 8wọ́n wí pé, “Ohun búburú ni ó dì mọ́ ọn ṣinṣin àti ní ibi tí ó dùbúlẹ̀ sí, kì yóò dìde mọ́.” 9Pàápàá, ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé, ẹni tí ó ń jẹ nínú oúnjẹ mi, tí gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sókè sí mi. 10Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa, ṣàánú fún mi; gbé mi sókè, kí ń ba lè san fún wọn. 11Èmi mọ̀ pé inú rẹ̀ dùn sí mi, nítorí ọ̀tá mi kò borí mi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.