Saamu 41:3
Psalms 41:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa yóò gbà á lórí àkéte àìsàn rẹ̀ yóò sì mú un padà bọ̀ sípò kúrò nínú àìsàn rẹ̀.
Psalms 41:3 in English
Psalms 41:3 · Berean Standard Bible
The LORD will sustain him on his bed of illness and restore him from his bed of sickness.
Context
1Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ń ro ti aláìní:
Olúwa yóò gbà á ní ìgbà ìpọ́njú. 2Olúwa yóò dáàbò bò ó yóò sì pa ọkàn rẹ̀ mọ́:
yóò bùkún fún un ní orí ilẹ̀
kò sì ní fi sílẹ̀ fún ìfẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀. 3Olúwa yóò gbà á lórí àkéte àìsàn rẹ̀
yóò sì mú un padà bọ̀ sípò kúrò nínú àìsàn rẹ̀. 4Ní ti èmi, mo wí pé “Olúwa, ṣàánú fún mi;
wò mí sàn, nítorí pé mo ti ṣẹ̀ sí ọ”. 5Àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ mi nínú àrankàn, pé,
“Nígbà wo ni yóò kú, ti orúkọ rẹ̀ yóò sì run?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.