Native Bible

Psalms 35:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Má ṣe jẹ́ kí wọn wí nínú ara wọn pé, “Háà! A ti rí ohun tí ọkàn wa ń fẹ́!” Má ṣe jẹ́ kí wọn kí ó wí pé, “A ti gbé e mì.”

Psalms 35:25 in English

Psalms 35:25 · Berean Standard Bible

Let them not say in their hearts, “Aha, just what we wanted!” Let them not say, “We have swallowed him up!”

Context

23Dìde! ru ara rẹ̀ sókè fún ààbò mi, àti sí ọ̀ràn mi, Ọlọ́run mi àti Olúwa mi! 24Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa Ọlọ́run mi, gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ, kí o má sì ṣe jẹ́ kí wọn kí ó yọ̀ lórí mi! 25Má ṣe jẹ́ kí wọn wí nínú ara wọn pé, “Háà! A ti rí ohun tí ọkàn wa ń fẹ́!” Má ṣe jẹ́ kí wọn kí ó wí pé, “A ti gbé e mì.” 26Kí ojú kí ó tì wọ́n, kí wọn kí ó sì dààmú pọ̀, àní àwọn tí ń yọ̀ sí ìyọnu mi kí a fi ìtìjú àti àbùkù wọ̀ wọ́n ní aṣọ tí ń gbéraga sí mi. 27Jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ ìdáláre mi fò fún ayọ̀ àti ìdùnnú; kí wọn máa sọ ọ́ títí lọ, “Pé gbígbéga ni Olúwa, sí àlàáfíà ìránṣẹ́ rẹ̀.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.