Saamu 28:1
Psalms 28:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ Olúwa, mo ké pe àpáta mi. Má ṣe kọ etí dídi sí mi. Tí ìwọ bá dákẹ́ sí mi, èmí yóò dàbí àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun.
Psalms 28:1 in English
Psalms 28:1 · Berean Standard Bible
To You, O LORD, I call; be not deaf to me, O my Rock. For if You remain silent, I will be like those descending to the Pit.
Context
1Ìwọ Olúwa,
mo ké pe àpáta mi.
Má ṣe kọ etí dídi sí mi.
Tí ìwọ bá dákẹ́ sí mi,
èmí yóò dàbí àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun. 2Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú,
bí mo ṣe ń ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́,
bí mo ṣe gbé àwọn ọwọ́ mi sókè
sí Ibi Mímọ́ rẹ Jùlọ. 3Má ṣe fà mí lọ pẹ̀lú ènìyàn búburú àti,
pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,
tí ń sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò wọn
ṣùgbọ́n tí ìwà ìkà ń bẹ nínú wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.