Saamu 150
Psalms 150 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
1Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Ẹ fi ìyìn fún Ọlọ́run ní ibi mímọ́ rẹ̀,
ẹ yìn ín nínú agbára ọ̀run rẹ̀. 2Ẹ yìn ín fún iṣẹ́ agbára rẹ̀.
Ẹ yìn ín fún títóbi rẹ̀ tí ó tayọ̀. 3Ẹ fi ohùn ìpè yìn ín.
Ẹ fi ohun èlò orin yìn ín. 4Ẹ fi ohun èlò orin àti ijó yìn ín
fi ohun èlò orin olókùn àti ìpè yìn ín, 5Ẹ yìn ín pẹ̀lú aro olóhùn òkè,
ẹ yìn ín lára aro olóhùn gooro. 6Jẹ́ kí gbogbo ohun tí ó ní ẹ̀mí yin Olúwa.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.