Native Bible

Psalms 144:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí àwọn ọmọkùnrin wa kí ó dàbí igi gbígbìn tí ó dàgbà ni ìgbà èwe wọn, àti ọmọbìnrin wa yóò dàbí òpó ilé tí a ṣe ọ̀nà sí bí àfarawé ààfin.

Psalms 144:12 in English

Psalms 144:12 · Berean Standard Bible

Then our sons will be like plants nurtured in their youth, our daughters like corner pillars carved to adorn a palace.

Context

10Òun ni ó fi ìgbàlà fún àwọn ọba, ẹni tí ó gba Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ idà ìpanilára. Lọ́wọ́ pípanirun. 11Gbà mí kí o sì yọ mí nínú ewu kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì tí ẹnu wọn kún fún èké, tí ọwọ́ ọ̀tún wọn jẹ́ ọwọ́ ọ̀tún èké. 12Kí àwọn ọmọkùnrin wa kí ó dàbí igi gbígbìn tí ó dàgbà ni ìgbà èwe wọn, àti ọmọbìnrin wa yóò dàbí òpó ilé tí a ṣe ọ̀nà sí bí àfarawé ààfin. 13Àká wa yóò kún pẹ̀lú gbogbo onírúurú oúnjẹ àgùntàn wa yóò pọ̀ si ní ẹgbẹ̀rún, ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní oko wa: 14àwọn màlúù wa yóò ru ẹrù wúwo kí ó má sí ìkọlù, kí ó má sí ìkólọ sí ìgbèkùn, kí ó má sí i igbe ìpọ́njú ní ìgboro wa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.