Native Bible

Psalms 143:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọ̀tá ń lépa mi, ó fún mi pamọ́ ilẹ̀; ó mú mi gbé nínú òkùnkùn bí àwọn tí ó ti kú ti pẹ́.

Psalms 143:3 in English

Psalms 143:3 · Berean Standard Bible

For the enemy has pursued my soul, crushing my life to the ground, making me dwell in darkness like those long since dead.

Context

1Olúwa gbọ́ àdúrà mi, fetísí igbe mi fún àánú; nínú òtítọ́ àti òdodo rẹ, wá fún ìrànlọ́wọ́ mi. 2Má ṣe mú ìránṣẹ́ rẹ wá sí ìdájọ́, nítorí kò sí ẹnìkan tí ó wà láààyè tí ó ṣe òdodo níwájú rẹ. 3Ọ̀tá ń lépa mi, ó fún mi pamọ́ ilẹ̀; ó mú mi gbé nínú òkùnkùn bí àwọn tí ó ti kú ti pẹ́. 4Nítorí náà ẹ̀mí mi ṣe rẹ̀wẹ̀sì nínú mi; ọkàn mi nínú mi ṣì pòruurù. 5Èmi rántí ọjọ́ tí ó ti pẹ́; èmi ń ṣe àṣàrò lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ mo sì ṣe àkíyèsí ohun tí ọwọ́ rẹ ti ṣe.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.