Saamu 14:2
Psalms 14:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run wá lórí àwọn ọmọ ènìyàn bóyá ó le rí ẹni tí òye yé, ẹnikẹ́ni tó ń wá Ọlọ́run.
Psalms 14:2 in English
Psalms 14:2 · Berean Standard Bible
The LORD looks down from heaven upon the sons of men to see if any understand, if any seek God.
Context
1Aṣiwèrè wí nínú ọkàn rẹ̀ pé,
“Ko sí Ọlọ́run.”
Wọ́n díbàjẹ́, iṣẹ́ wọn sì burú;
kò sí ẹnìkan tí yóò ṣe rere. 2Olúwa sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run wá
lórí àwọn ọmọ ènìyàn
bóyá ó le rí ẹni tí òye yé,
ẹnikẹ́ni tó ń wá Ọlọ́run. 3Gbogbo wọn sì ti yípadà, gbogbo wọn sì ti díbàjẹ́;
kò sì ṣí ẹni tí ó ń ṣe rere,
kò sí ẹnìkan. 4Ǹjẹ́ olùṣe búburú kò ha ní ìmọ̀?
Àwọn tí ó ń pa ènìyàn mi jẹ bí ẹní jẹun;
wọn kò sì ké pe Olúwa?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.