Native Bible

Psalms 135:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Sihoni, ọba àwọn ará Amori, àti Ogu, ọba Baṣani, àti gbogbo ìjọba Kenaani:

Psalms 135:11 in English

Psalms 135:11 · Berean Standard Bible

Sihon king of the Amorites, Og king of Bashan, and all the kings of Canaan.

Context

9Ẹni tí ó rán iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu sí àárín rẹ̀, ìwọ Ejibiti, sí ara Farao àti sí ara àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gbogbo. 10Ẹni tí ó kọlu àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀, tí ó sì pa àwọn alágbára ọba. 11Sihoni, ọba àwọn ará Amori, àti Ogu, ọba Baṣani, àti gbogbo ìjọba Kenaani: 12Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní, ìní fún Israẹli, ènìyàn rẹ̀. 13Olúwa orúkọ rẹ dúró láéláé; ìrántí rẹ Olúwa, láti ìrandíran.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.