Native Bible

Proverbs 8:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

nígbà tí ó ṣe ààlà fún omi Òkun kí omi má ba à kọjá ààlà àṣẹ rẹ̀, àti nígbà tí ó pààlà ìpìlẹ̀ ayé.

Proverbs 8:29 in English

Proverbs 8:29 · Berean Standard Bible

when He set a boundary for the sea, so that the waters would not surpass His command, when He marked out the foundations of the earth.

Context

27Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn, nígbà tí ó fi òsùwọ̀n àyíká sórí ibú omi, 28nígbà tí ó ṣẹ̀dá òfúrufú lókè tí ó sì fi orísun ibú omi sí ipò rẹ̀ láì le è yẹsẹ̀, 29nígbà tí ó ṣe ààlà fún omi Òkun kí omi má ba à kọjá ààlà àṣẹ rẹ̀, àti nígbà tí ó pààlà ìpìlẹ̀ ayé. 30Nígbà náà èmi ni gbẹ́nàgbẹ́nà ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mo kún fún inú dídùn lójoojúmọ́, mo ń yọ̀ nígbà gbogbo níwájú rẹ̀. 31Mo ń yọ̀ nínú gbogbo àgbáyé tí ó dá mo sì ní inú dídùn sí àwọn ọmọ ènìyàn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.