Òwe 27:24
Proverbs 27:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
nítorí ọrọ̀ kì í pẹ́ lọ títí adé kì í sì í wà lórí títí láéláé.
Proverbs 27:24 in English
Proverbs 27:24 · Berean Standard Bible
for riches are not forever, nor does a crown endure to every generation.
Context
22Bí a tilẹ̀ gún aláìgbọ́n nínú odó,
fi ọmọ odó gún un bí èlùbọ́
ìwọ kì yóò le è yọ ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ kúrò ní inú rẹ̀. 23Rí i dájú pé o mọ ipò tí àwọn agbo àgùntàn rẹ wà
bojútó àwọn agbo màlúù rẹ dáradára; 24nítorí ọrọ̀ kì í pẹ́ lọ títí
adé kì í sì í wà lórí títí láéláé. 25Nígbà tí a bá kó koríko, ewéko tuntun yóò sì hù jáde, a ó sì kó koríko àwọn orí òkè wọlé 26àwọn àgùntàn yóò pèsè aṣọ fún ọ,
àti ewúrẹ́ yóò pèsè owó oko.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.