Òwe 17:3
Proverbs 17:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Iná ni a fi fọ́ fàdákà àti wúrà, ṣùgbọ́n Olúwa ló ń dán ọkàn wò.
Proverbs 17:3 in English
Proverbs 17:3 · Berean Standard Bible
A crucible for silver and a furnace for gold, but the LORD is the tester of hearts.
Context
1Òkèlè gbígbẹ tòun tàlàáfíà àti ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ sàn
ju ilé tí ó kún fọ́fọ́ fún ẹran àti ìjà. 2Ọlọ́gbọ́n ìránṣẹ́ yóò ṣàkóso adójútini ọmọ,
yóò sì pín ogún gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ. 3Iná ni a fi fọ́ fàdákà àti wúrà,
ṣùgbọ́n Olúwa ló ń dán ọkàn wò. 4Ènìyàn búburú ń tẹ́tí sí ètè tí ń sọ ibi;
òpùrọ́ a máa fetí sí ahọ́n búburú. 5Ẹnikẹ́ni tí ó bá sín olùpọ́njú jẹ, ó gan Ẹlẹ́dàá rẹ̀,
ẹnikẹ́ni tí ń yọ̀ sí ìyọnu kò ní lọ láìjìyà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.