Òwe 15:23
Proverbs 15:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Inú ènìyàn a máa dùn nígbà tí ó bá fèsì tó yẹ ọ̀rọ̀ tí ó bá sì wá lásìkò tó yẹ dára púpọ̀!
Proverbs 15:23 in English
Proverbs 15:23 · Berean Standard Bible
A man takes joy in a fitting reply— and how good is a timely word!
Context
21Inú ènìyàn aláìlóye a máa dùn sí ìwà òmùgọ̀;
ṣùgbọ́n olóye ènìyàn a máa rin ọ̀nà tààrà. 22Ìgbèrò a máa dasán níbi tí kò sí ìmọ̀ràn;
ṣùgbọ́n a máa yege níbi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùbádámọ̀ràn wà. 23Inú ènìyàn a máa dùn nígbà tí ó bá fèsì tó yẹ
ọ̀rọ̀ tí ó bá sì wá lásìkò tó yẹ dára púpọ̀! 24Ọ̀nà ìyè ń lọ sókè fún ọlọ́gbọ́n
láti sọ kí ó má bá à sọ̀kalẹ̀ lọ sí ipò òkú. 25Olúwa fa ilé onígbèéraga ya lulẹ̀,
ṣùgbọ́n ó pa ààlà opó onírẹ̀lẹ̀ mọ́ láìyẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.