Native Bible

Proverbs 11:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí òrùka wúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀ ni arẹwà obìnrin tí kò lọ́gbọ́n.

Proverbs 11:22 in English

Proverbs 11:22 · Berean Standard Bible

Like a gold ring in a pig’s snout is a beautiful woman who lacks discretion.

Context

20Olúwa kórìíra àwọn ènìyàn ọlọ́kàn búburú ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn tí ọ̀nà wọn kò lábùkù. 21Mọ èyí dájú pé, ènìyàn búburú kì yóò lọ láìjìyà, ṣùgbọ́n àwọn olódodo yóò lọ láìjìyà. 22Bí òrùka wúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀ ni arẹwà obìnrin tí kò lọ́gbọ́n. 23Ìfẹ́ inú olódodo yóò yọrí sí ohun rere ṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn búburú yóò yọrí sí ìbínú. 24Ènìyàn kan ń fún ni lọ́fẹ̀ẹ́, síbẹ̀ ó ń ní sí i; òmíràn ń háwọ́ ju bí ó ti yẹ ṣùgbọ́n ó di aláìní.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.