Òwe 10:16
Proverbs 10:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èrè olódodo ń mú ìyè wá fún wọn, ṣùgbọ́n èrè ènìyàn búburú ń mú ìjìyà wá fún wọn.
Proverbs 10:16 in English
Proverbs 10:16 · Berean Standard Bible
The labor of the righteous leads to life, but the gain of the wicked brings punishment.
Context
14Ọlọ́gbọ́n ènìyàn kó ìmọ̀ jọ,
ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n a máa ṣokùnfà ìparun. 15Ọrọ̀ àwọn olódodo ni ìlú olódi wọn,
ṣùgbọ́n òsì ni ìparun aláìní. 16Èrè olódodo ń mú ìyè wá fún wọn,
ṣùgbọ́n èrè ènìyàn búburú ń mú ìjìyà wá fún wọn. 17Ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí fi ọ̀nà sí ìyè hàn,
ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ ìbáwí mú àwọn mìíràn ṣìnà. 18Ẹni tí ó pa ìkórìíra rẹ̀ mọ́ jẹ́ òpùrọ́
ẹni tí ó sì ń ba ni jẹ́ jẹ́ aláìgbọ́n.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.