Native Bible

Proverbs 1:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí ìyọnu bá dé bá a yín bí ìjì líle, nígbà tí ìdààmú bá dé bá ọ bí ààjà, nígbà tí wàhálà àti ìbànújẹ́ ọkàn bá bò ọ́ mọ́lẹ̀.

Proverbs 1:27 in English

Proverbs 1:27 · Berean Standard Bible

when your dread comes like a storm, and your destruction like a whirlwind, when distress and anguish overwhelm you.

Context

25níwọ́n bí ẹ ti kọ gbogbo ìmọ̀ràn mi, tí ẹ̀yin kò sì gba ìbáwí mi, 26Èmi pẹ̀lú yóò fi ìdààmú yín rẹ́rìn-ín; èmi yóò ṣẹ̀fẹ̀ nígbà tí ìyọnu bá dé bá a yín. 27Nígbà tí ìyọnu bá dé bá a yín bí ìjì líle, nígbà tí ìdààmú bá dé bá ọ bí ààjà, nígbà tí wàhálà àti ìbànújẹ́ ọkàn bá bò ọ́ mọ́lẹ̀. 28“Nígbà náà ni wọn yóò ké pè mí ṣùgbọ́n, èmi kò ní dáhùn; wọn yóò fi ara balẹ̀ wá mi ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí mi. 29Níwọ́n bí wọ́n ti kórìíra ìmọ̀ tí wọ́n sì kọ̀ láti bẹ̀rù Olúwa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.