Native Bible

Philippians 3:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítòótọ́ láìṣe àní àní mo sì ka ohun gbogbo sí òfo nítorí ìtayọ ìmọ̀ Kristi Jesu Olúwa mi; nítorí ẹni ti mo ti ṣòfò ohun gbogbo, mo si kà wọn sí ohun tí kò ní èrè, kí èmi lè jèrè Kristi,

Philippians 3:8 in English

Philippians 3:8 · Berean Standard Bible

More than that, I count all things as loss compared to the surpassing excellence of knowing Christ Jesus my Lord, for whom I have lost all things. I consider them rubbish, that I may gain Christ

Context

6ní ti ìtara, èmi ń ṣe inúnibíni sí ìjọ; ní ti òdodo tí ó wà nínú òfin, mo jẹ́ aláìlẹ́gàn. 7Ṣùgbọ́n ohunkóhun tí ó ti jásí èrè fún mi, àwọn ni mo ti kà sí òfo nítorí Kristi. 8Nítòótọ́ láìṣe àní àní mo sì ka ohun gbogbo sí òfo nítorí ìtayọ ìmọ̀ Kristi Jesu Olúwa mi; nítorí ẹni ti mo ti ṣòfò ohun gbogbo, mo si kà wọn sí ohun tí kò ní èrè, kí èmi lè jèrè Kristi, 9kí a sì lè bá mi nínú rẹ̀, láìní òdodo tí èmi tìkára mi, tí ó ti inú òfin wá, ṣùgbọ́n èyí tí ó ti inú ìgbàgbọ́ wá nínú Kristi, òdodo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ ìgbàgbọ́. 10Èmi mọ̀ ọ́n, àti agbára àjíǹde rẹ̀, àti láti jẹ́ alábápín nínú ìyà rẹ̀ nígbà tí mo bá fi ara mọ́ ọn nínú ikú rẹ̀;

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.