Filipi 3:11
Philippians 3:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
nípasẹ̀ bẹ́ẹ̀ kí èmi lè ní àjíǹde kúrò nínú òkú.
Philippians 3:11 in English
Philippians 3:11 · Berean Standard Bible
and so, somehow, to attain to the resurrection from the dead.
Context
9kí a sì lè bá mi nínú rẹ̀, láìní òdodo tí èmi tìkára mi, tí ó ti inú òfin wá, ṣùgbọ́n èyí tí ó ti inú ìgbàgbọ́ wá nínú Kristi, òdodo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ ìgbàgbọ́. 10Èmi mọ̀ ọ́n, àti agbára àjíǹde rẹ̀, àti láti jẹ́ alábápín nínú ìyà rẹ̀ nígbà tí mo bá fi ara mọ́ ọn nínú ikú rẹ̀; 11nípasẹ̀ bẹ́ẹ̀ kí èmi lè ní àjíǹde kúrò nínú òkú. 12Kì í ṣe pé ọwọ́ mi ti tẹ̀ ẹ́ ná, tàbí mo ti di pípé, ṣùgbọ́n èmi ń lépa sí i, bí ọwọ́ mi yóò lè tẹ èrè náà nítorí èyí tí a ti dì mímú pẹ̀lú, láti ọ̀dọ̀ Kristi Jesu wá. 13Ará, èmi kò kara mi sí ẹni ti ọwọ́ rẹ̀ ti tẹ̀ ẹ́ ná, ṣùgbọ́n ohun kan yìí ni èmi ń ṣe, èmi ń gbàgbé àwọn nǹkan tí ó ti kọjá. Lẹ́yìn náà mo ń nàgà wo àwọn nǹkan tí ó wà níwájú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.