Native Bible

Philippians 2:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì wà ní àwòrán ènìyàn, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, o sì tẹríba títí de ojú ikú, àní ikú lórí àgbélébùú.

Philippians 2:8 in English

Philippians 2:8 · Berean Standard Bible

And being found in appearance as a man, He humbled Himself and became obedient to death— even death on a cross.

Context

6Ẹni tí, bí o tilẹ̀ jẹ́ ìrísí Ọlọ́run, kò kà á sí ohun tí ìbá fi ìwọra gbámú láti bá Ọlọ́run dọ́gba. 7Ṣùgbọ́n ó bọ́ ògo rẹ̀ sílẹ̀, ó sì mú àwọ̀ ìránṣẹ́, a sì ṣe é ni àwòrán ènìyàn. 8Ó sì wà ní àwòrán ènìyàn, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, o sì tẹríba títí de ojú ikú, àní ikú lórí àgbélébùú. 9Nítorí náà, Ọlọ́run ti gbé e ga sí ipele tí ó ga jùlọ, ó sì ti fi orúkọ kan ti ó borí gbogbo orúkọ fún un, 10pé ni orúkọ Jesu ni kí gbogbo eékún máa wólẹ̀, ní ọ̀run, àti ní orí ilẹ̀ ayé àti ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.