Filipi 2:26
Philippians 2:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí tí ọkàn rẹ̀ fà sí gbogbo yín, ó sì kún fún ìbànújẹ́, nítorí tí ẹ̀yin gbọ́ pé ó ṣe àìsàn.
Philippians 2:26 in English
Philippians 2:26 · Berean Standard Bible
For he has been longing for all of you and is distressed because you heard he was ill.
Context
24Ṣùgbọ́n mo ní gbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa, pé èmi tìkára mi pẹ̀lú yóò wá ní àìpẹ́. 25Mo kà á sí pé n kò lè ṣàìrán Epafiroditu arákùnrin mi sí yín, àti olùbáṣiṣẹ́ pọ̀ mi, àti ọmọ-ogun ẹlẹgbẹ́ mi, ìránṣẹ́ yín pẹ̀lú, tí ẹ rán láti ṣè ránṣẹ́ fún mi nínú àìní mi. 26Nítorí tí ọkàn rẹ̀ fà sí gbogbo yín, ó sì kún fún ìbànújẹ́, nítorí tí ẹ̀yin gbọ́ pé ó ṣe àìsàn. 27Nítòótọ́ ni ó ti ṣe àìsàn títí dé ojú ikú, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti ṣàánú fún un; kì í sì í ṣe fún òun nìkan, ṣùgbọ́n fún èmi pẹ̀lú kí èmi má ṣe ni ìbànújẹ́ lórí ìbànújẹ́. 28Nítorí náà ni mo ṣe ní ìtara láti rán an, pé nígbà tí ẹ̀yin bá sì tún rí i, kí ẹ̀yin lè yọ̀ àti kí ìkáyà sókè mi lè dínkù.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.